Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran.
Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi?
Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu.
Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro.
Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yapa si ara rẹ̀; ijọba rẹ̀ yio ha ṣe le duro?
Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina ni nwọn o fi ma ṣe onidajọ nyin.
Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin.
Tabi ẹnikan yio ti ṣe wọ̀ ile alagbara lọ, ki o si kó o li ẹrù, bikoṣepe o kọ́ dè alagbara na? nigbana ni yio si kó o ni ile.
Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka.
Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia.
Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀.
Sọ igi di rere, eso rẹ̀ a si di rere; tabi sọ igi di buburu, eso rẹ̀ a si di buburu: nitori nipa eso li ã fi mọ igi.
Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ.
Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá.
Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.
Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi.