YouVersion Logo
Search Icon

Luk 15:11, 12, 13, 14, 16, 17, 18, 19, 20, 21, 22, 23, 24, 25, 26, 27, 28, 29, 30, 31, 32

Luk 15:11 YBCV

O si wipe, Ọkunrin kan li ọmọkunrin meji

Luk 15:12 YBCV

Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn.

Luk 15:13 YBCV

Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.

Luk 15:14 YBCV

Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini.

Luk 15:16 YBCV

Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u.

Luk 15:17 YBCV

Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin.

Luk 15:18 YBCV

Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ

Luk 15:19 YBCV

Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ.

Luk 15:20 YBCV

O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.

Luk 15:21 YBCV

Ọmọ na si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi kò yẹ li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́.

Luk 15:22 YBCV

Ṣugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mu ãyo aṣọ wá kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ; ẹ si fi oruka bọ̀ ọ lọwọ, ati bàta si ẹsẹ rẹ̀

Luk 15:23 YBCV

Ẹ si mu ẹgbọ̀rọ malu abọpa wá, ki ẹ si pa a; ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya

Luk 15:24 YBCV

Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i. Nwọn si bẹ̀re si iṣe ariya.

Luk 15:25 YBCV

Ṣugbọn ọmọ rẹ̀ eyi ẹgbọn ti wà li oko: bi o si ti mbọ̀, ti o sunmọ eti ile, o gbọ́ orin on ijó.

Luk 15:26 YBCV

O si pè ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ wọn, o bère, kili ã mọ̀ nkan wọnyi si?

Luk 15:27 YBCV

O si wi fun u pe, Aburo rẹ de; baba rẹ si pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa, nitoriti o ri i pada li alafia ati ni ilera.

Luk 15:28 YBCV

O si binu, o si kọ̀ lati wọle; baba rẹ̀ si jade, o si wá iṣipẹ fun u.

Luk 15:29 YBCV

O si dahùn o wi fun baba rẹ̀ pe, Wo o, lati ọdún melo wọnyi li emi ti nsin ọ, emi kò si ru ofin rẹ ri: iwọ kò si ti ifi ọmọ ewurẹ kan fun mi, lati fi ba awọn ọrẹ́ mi ṣe ariya

Luk 15:30 YBCV

Ṣugbọn nigbati ọmọ rẹ yi de, ẹniti o fi panṣaga run ọrọ̀ rẹ, iwọ si ti pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa fun u.

Luk 15:31 YBCV

O si wi fun u pe, Ọmọ, nigbagbogbo ni iwọ mbẹ lọdọ mi, ohun gbogbo ti mo si ni, tìrẹ ni.

Luk 15:32 YBCV

O yẹ ki a ṣe ariya ki a si yọ̀: nitori aburo rẹ yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i.