Joh 6:61, 62, 63, 64, 65, 66, 67, 68, 69, 70, 71
Joh 6:61 YBCV
Nigbati Jesu si mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nkùn si ọ̀rọ na, o wi fun wọn pe, Eyi jẹ ikọsẹ̀ fun nyin bi?
Joh 6:62 YBCV
Njẹ, bi ẹnyin ba si ri ti Ọmọ-enia ngòke lọ sibi ti o gbé ti wà ri nkọ́?
Joh 6:63 YBCV
Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni.
Joh 6:64 YBCV
Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn.
Joh 6:65 YBCV
O si wipe, Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, kò si ẹniti o le tọ̀ mi wá, bikoṣepe a fifun u lati ọdọ Baba mi wá.
Joh 6:66 YBCV
Nitori eyi ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pada sẹhin, nwọn kò si bá a rìn mọ́.
Joh 6:68 YBCV
Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? Iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun.
Joh 6:69 YBCV
Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.
Joh 6:70 YBCV
Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin mejila kọ́ ni mo yàn, ọkan ninu nyin kò ha si yà Èṣu?
Joh 6:71 YBCV
O nsọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni: nitoripe on li ẹniti yio fi i hàn, ọkan ninu awọn mejila.