YouVersion Logo
Search Icon

Joh 2:1, 3, 4, 5, 6, 7, 8, 9, 10, 11, 12, 13, 14, 15, 16, 17, 18, 19, 20, 21, 22

Joh 2:1 YBCV

NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀

Joh 2:3 YBCV

Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini.

Joh 2:4 YBCV

Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de.

Joh 2:5 YBCV

Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e.

Joh 2:6 YBCV

Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta.

Joh 2:7 YBCV

Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti.

Joh 2:8 YBCV

O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ.

Joh 2:9 YBCV

Bi olori àse si ti tọ́ omi ti a sọ di waini wò, ti ko si mọ̀ ibi ti o ti wá (ṣugbọn awọn iranṣẹ ti o bù omi na wá mọ̀), olori àse pè ọkọ iyawo

Joh 2:10 YBCV

O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi.

Joh 2:11 YBCV

Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.

Joh 2:12 YBCV

Lẹhin eyi, o sọkalẹ lọ si Kapernamu, on ati iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nwọn kò si gbé ibẹ̀ li ọjọ pupọ.

Joh 2:13 YBCV

Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu

Joh 2:14 YBCV

O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko

Joh 2:15 YBCV

O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu.

Joh 2:16 YBCV

O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità.

Joh 2:17 YBCV

Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ranti pe, a ti kọ ọ pe, Itara ile rẹ jẹ mi run.

Joh 2:18 YBCV

Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi?

Joh 2:19 YBCV

Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ wó tẹmpili yi palẹ̀, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró.

Joh 2:20 YBCV

Nigbana li awọn Ju wipe, Ọdún mẹrindiladọta li a fi kọ́ tẹmpili yi, iwọ o ha si gbé e ró ni ijọ mẹta?

Joh 2:21 YBCV

Ṣugbọn on nsọ ti tẹmpili ara rẹ̀.

Joh 2:22 YBCV

Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ.