Jer 46
46
Nebukadinesari ṣẹgun Ijipti ní Kakemiṣi
1Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah, woli wá si awọn orilẹ-ède.
2Si Egipti, si ogun Farao-Neko, ọba Egipti, ti o wà lẹba odò Ferate ni iha Karkemiṣi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kọlu ni ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda.
3Ẹ mura apata ati asà, ẹ si sunmọ tosi si oju ìja,
4Ẹ di ẹṣin ni gãrì; ẹ gùn wọn, ẹnyin ẹlẹṣin, ẹ duro lẹsẹsẹ ninu akoro nyin; ẹ dan ọ̀kọ, ẹ wọ ẹwu irin.
5Ẽṣe ti emi ti ri wọn ni ibẹ̀ru ati ni ipẹhinda? awọn alagbara wọn li a lù bolẹ, nwọn sa, nwọn kò si wò ẹhin: ẹ̀ru yika kiri, li Oluwa wi.
6Ẹni ti o yara, kì yio salọ, alagbara ọkunrin kì yio si sala: ni iha ariwa lẹba odò Ferate ni nwọn o kọsẹ̀, nwọn o si ṣubu.
7Tani eyi ti o goke wá bi odò, ti omi rẹ̀ nrú gẹgẹ bi odò wọnni?
8Egipti dide bi odò Nile, omi rẹ̀ si nrú bi omi odò wọnni; o si wipe, Emi o goke lọ, emi o si bò ilẹ aiye, emi o si pa ilu ati awọn olugbe inu rẹ̀ run!
9Ẹ goke wá, ẹnyin ẹṣin, ẹ si sare kikan, ẹnyin kẹ̀kẹ; ki awọn alagbara si jade wá; awọn ara Etiopia, ati awọn ara Libia, ti o ndi asà mu; ati awọn ara Lidia ti nmu ti o nfa ọrun.
10Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate.
11Goke lọ si Gileadi, ki o si mu ikunra, iwọ wundia, ọmọbinrin Egipti: li asan ni iwọ o lò ọ̀pọlọpọ õgùn; ọja-imularada kò si fun ọ.
12Awọn orilẹ-ède ti gbọ́ itiju rẹ, igbe rẹ si ti kún ilẹ na: nitori alagbara ọkunrin ti kọsẹ lara alagbara, ati awọn mejeji si jumọ ṣubu pọ̀.
Bíbọ̀ Nebukadinesari
13Ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun Jeremiah, woli, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli wá lati kọlu ilẹ Egipti.
14Ẹ sọ ọ ni Egipti, ki ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Migdoli, ẹ si jẹ ki a gbọ́ ni Nofu ati Tafanesi: ẹ wipe, duro lẹsẹsẹ, ki o si mura, nitori idà njẹrun yi ọ kakiri.
15Ẽṣe ti a fi gbá awọn akọni rẹ lọ? nwọn kò duro, nitori Oluwa le wọn.
16A sọ awọn ti o kọsẹ di pupọ, lõtọ, ẹnikini ṣubu le ori ẹnikeji: nwọn si wipe, Dide, ẹ jẹ ki a pada lọ sọdọ awọn enia wa, ati si ilẹ ti a bi wa, kuro lọwọ idá aninilara.
17Nwọn kigbe nibẹ; Farao, ọba Egipti ti ṣegbe: on ti kọja akoko ti a dá!
18Bi emi ti wà, li Ọba, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, nitõtọ gẹgẹ bi Tabori lãrin awọn oke, ati gẹgẹ bi Karmeli lẹba okun, bẹ̃ni on o de.
19Iwọ, ọmọbinrin ti ngbe Egipti, pèse ohun-èlo ìrin-ajo fun ara rẹ: nitori Nofu yio di ahoro, a o si fi joná, laini olugbe.
20Ẹgbọrọ malu ti o dara pupọ ni Egipti, lõtọ, iparun de, o de lati ariwa!
21Awọn ologun rẹ̀ ti a fi owo bẹ̀, dabi akọmalu abọpa lãrin rẹ̀; awọn wọnyi pẹlu yi ẹhin pada; nwọn jumọ sa lọ pọ: nwọn kò duro, nitoripe ọjọ wàhala wọn de sori wọn, àkoko ibẹwo wọn.
22Ohùn inu rẹ̀ yio lọ gẹgẹ bi ti ejo; nitori nwọn o lọ pẹlu agbara; pẹlu àkeke lọwọ ni nwọn tọ̀ ọ wá bi awọn akégi.
23Nwọn o ke igbo rẹ̀ lulẹ, li Oluwa wi, nitori ti a kò le ridi rẹ̀; nitoripe nwọn pọ̀ jù ẹlẹnga lọ, nwọn si jẹ ainiye.
24Oju yio tì ọmọbinrin Egipti; a o fi i le ọwọ awọn enia ariwa.
25Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe; Wò o, emi o bẹ̀ Amoni ti No, ati Farao, ati Egipti wò, pẹlu awọn ọlọla wọn, ati awọn ọba wọn; ani Farao ati gbogbo awọn ti o gbẹkẹ le e:
26Emi o si fi wọn le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati le ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀: lẹhin na, a o si mã gbe inu rẹ̀, gẹgẹ bi ìgba atijọ, li Oluwa wi.
OLUWA Yóo Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là
27Ṣugbọn iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, má si fòya, iwọ Israeli: nitori, wo o, emi o gbà ọ là lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati ilẹ ìgbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì o si dẹ̀ru bà a.
28Iwọ má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu rẹ; nitori emi o ṣe opin patapata ni gbogbo awọn orilẹ-ède, nibiti emi ti le ọ si: ṣugbọn emi kì o ṣe ọ li opin patapata, ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn; sibẹ emi kì yio jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 46: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.