NIGBANA ni gbogbo awọn olori ogun, ati Johanani, ọmọ Karea, ati Jesaniah, ọmọ Hoṣaiah, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere de ẹni-nla, nwọn wá,
Nwọn si sọ fun Jeremiah woli, pe, Awa bẹ ọ, jẹ ki ẹ̀bẹ wa ki o wá siwaju rẹ, ki o si gbadura fun wa si Oluwa Ọlọrun rẹ, ani fun gbogbo iyokù yi; (nitori lati inu ọ̀pọlọpọ, diẹ li awa kù, gẹgẹ bi oju rẹ ti ri wa:)
Ki Oluwa Ọlọrun rẹ le fi ọ̀na hàn wa ninu eyi ti awa iba rìn, ati ohun ti awa iba ṣe.
Jeremiah, woli, si wi fun wọn pe, emi gbọ́; wò o, emi o gbadura si Oluwa Ọlọrun nyin gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin; yio si ṣe, pe ohunkohun ti Oluwa yio fi da nyin lohùn emi o sọ ọ fun nyin; emi kì o ṣẹ nkankan kù fun nyin.
Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa.
Iba ṣe rere, iba ṣe ibi, awa o gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, sọdọ ẹniti awa rán ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.
O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá.
Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla.
O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀;
Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin.
Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀.
Emi o si fi ãnu hàn fun nyin, ki on ki o le ṣãnu fun nyin, ki o si mu ki ẹnyin pada si ilẹ nyin.