Jer 37
37
Ohun Tí Sedekiah Bèèrè lọ́wọ́ Jeremiah
1SEDEKIAH, ọmọ Josiah si jọba ni ipo Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ẹniti Nebukadnessari, ọba Babeli, fi jẹ ọba ni ilẹ Juda.
2Ṣugbọn ati on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia ilẹ na, kò fetisi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa Jeremiah, woli.
3Sedekiah, ọba si ran Jehukali, ọmọ Ṣelemiah, ati Ṣefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, si Jeremiah woli, wipe: Njẹ, bẹbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun wa fun wa.
4Jeremiah si nwọle o si njade lãrin awọn enia: nitori nwọn kò ti ifi i sinu tubu.
5Ogun Farao si jade lati Egipti wá: nigbati awọn ara Kaldea ti o dótì Jerusalemu si gbọ́ iró wọn, nwọn lọ kuro ni Jerusalemu.
6Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah, woli wá, wipe,
7Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi pe, Bayi li ẹnyin o sọ fun ọba Juda, ti o rán nyin si mi, lati bere lọwọ mi: Wò o, ogun Farao ti o jade lati ràn nyin lọwọ, yio pada si ilẹ rẹ̀, ani Egipti.
8Awọn ara Kaldea yio si tun wá, nwọn o si ba ilu yi jà, nwọn o kó o, nwọn o si fi iná kún u.
9Bayi li Oluwa wi; Ẹ máṣe tan ọkàn nyin jẹ, wipe, Ni lilọ awọn ara Kaldea yio lọ kuro lọdọ wa: nitoriti nwọn kì yio lọ.
10Nitori bi o tilẹ jẹ pe, ẹnyin lu gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti mba nyin jà bolẹ, ti o si jẹ pe awọn ọkunrin ti o gbọgbẹ li o kù ninu wọn: sibẹ nwọn o dide, olukuluku ninu agọ rẹ̀, nwọn o si fi iná kun ilu yi.
Wọ́n Mú Jeremiah, Wọ́n sì Tì Í Mọ́lé
11O si ṣe, nigbati ogun awọn ara Kaldea goke lọ kuro ni Jerusalemu nitori ogun Farao,
12Ni Jeremiah jade kuro ni Jerusalemu lati lọ si ilẹ Benjamini lati pin ini lãrin awọn enia.
13Nigbati o si wà li ẹnu-bode Benjamini, balogun iṣọ kan wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Irijah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Hananiah; on si mu Jeremiah woli, wipe, Iwọ nsa tọ̀ awọn ara Kaldea lọ.
14Jeremiah si wipe: Eke! emi kò sa tọ awọn ara Kaldea lọ. Ṣugbọn kò gbọ́ tirẹ̀: bẹ̃ni Irijah mu Jeremiah, o si mu u tọ̀ awọn ijoye wá.
15Nitorina ni awọn ijoye ṣe binu si Jeremiah, nwọn si lù u, nwọn si fi sinu tubu ni ile Jonatani, akọwe; nitori nwọn ti fi eyi ṣe ile túbu.
16Bẹ̃ni Jeremiah lọ inu ile-túbu ati inu iyara ṣiṣokunkun. Jeremiah si wà nibẹ li ọjọ pupọ;
17Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli.
18Pẹlupẹlu Jeremiah sọ fun Sedekiah, ọba, pe; Ẹṣẹ wo ni mo ṣẹ̀ ọ, tabi awọn iranṣẹ rẹ, tabi awọn enia yi, ti ẹnyin fi mi sinu ile-túbu?
19Nibo ni awọn woli nyin ha wà nisisiyi, awọn ti nsọtẹlẹ fun nyin, wipe, Ọba Babeli kì yio wá sọdọ nyin ati si ilẹ yi?
20Nitorina gbọ́ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀bẹ mi, emi bẹ̀ ọ, ki o wá si iwaju rẹ; ki iwọ ki o má jẹ ki emi pada si ile Jonatani akọwe, ki emi má ba kú nibẹ.
21Sedekiah, ọba, si paṣẹ pe ki nwọn ki o fi Jeremiah pamọ sinu agbala ile-túbu, ati pe ki nwọn ki o ma fun u ni iṣu akara kọ̃kan lojojumọ, lati ita awọn alakara, titi gbogbo akara fi tan ni ilu. Jeremiah si wà li agbala ile-túbu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 37: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.