Jer 36
36
Baruku Ka Àkọsílẹ̀ ninu Ilé OLUWA
1O si ṣe li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe,
2Mu iwe-kiká fun ara rẹ̀, ki o si kọ sinu rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ ti emi ti sọ si Israeli, ati si Juda, ati si gbogbo orilẹ-ède, lati ọjọ ti mo ti sọ fun ọ, lati ọjọ Josiah titi di oni yi.
3O le jẹ pe ile Juda yio gbọ́ gbogbo ibi ti mo pinnu lati ṣe si wọn; ki nwọn ki o le yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀; ki emi ki o dari aiṣedede wọn ati ẹ̀ṣẹ wọn ji wọn.
4Nigbana ni Jeremiah pè Baruku, ọmọ Neriah; Baruku si kọ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun u, sori iwe-kiká na.
5Jeremiah si paṣẹ fun Baruku pe, a se mi mọ: emi kò le lọ si ile Oluwa:
6Nitorina iwọ lọ, ki o si kà ninu iwe-kika na, ti iwọ kọ lati ẹnu mi wá, ọ̀rọ Oluwa li eti awọn enia ni ile Oluwa li ọjọ ãwẹ: ati pẹlu, iwọ o si kà a li eti gbogbo Juda, ti nwọn jade wá lati ilu wọn.
7O le jẹ pe, ẹ̀bẹ wọn yio wá siwaju Oluwa, nwọn o si yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀: nitoripe nla ni ibinu ati irunu ti Oluwa ti sọ si awọn enia yi.
8Baruku, ọmọ Neriah, si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jeremiah, woli, ti palaṣẹ fun u, lati ka ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe ni ile Oluwa.
9O si ṣe li ọdun karun Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, li oṣu kẹsan ni nwọn kede ãwẹ niwaju Oluwa, fun gbogbo enia ni Jerusalemu: ati fun gbogbo awọn enia ti o wá lati ilu Juda, si Jerusalemu.
10Baruku si ka ọ̀rọ Jeremiah lati inu iwe ni ile Oluwa, ni iyara Gemariah, ọmọ Ṣafani, akọwe, ni àgbala oke, nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa li eti gbogbo enia.
Wọ́n ka Àkọsílẹ̀ náà sí Etígbọ̀ọ́ Àwọn Ìjòyè
11Nigbati Mikaiah, ọmọ Gemariah, ọmọ Ṣafani, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe na wá,
12O si sọkalẹ lọ si ile ọba, sinu iyara akọwe, si wò o, gbogbo awọn ijoye joko nibẹ, Eliṣama, akọwe, ati Delaiah, ọmọ Semaiah, ati Elnatani, ọmọ Akbori, ati Gemariah, ọmọ Safani, ati Sedekiah, ọmọ Hananiah, ati gbogbo awọn ijoye.
13Nigbana ni Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ wọnni ti o ti gbọ́, fun wọn, nigbati Baruku kà lati inu iwe na li eti awọn enia.
14Nigbana ni gbogbo awọn ìjoye rán Jehudu, ọmọ Netaniah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Kuṣi, si Baruku wipe, Mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ, lati inu eyiti iwọ kà li eti awọn enia, ki o si wá. Nigbana ni Baruku, ọmọ Neriah, mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ̀, o si wá si ọdọ wọn.
15Nwọn si wi fun u pe, Joko nisisiyi, ki o si kà a li eti wa. Baruku si kà a li eti wọn.
16Njẹ, o si ṣe, nigbati nwọn gbọ́ gbogbo ọ̀rọ na, nwọn warìri, ẹnikini si ẹnikeji rẹ̀, nwọn si wi fun Baruku pe, Awa kò le ṣe aisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun ọba.
17Nwọn si bi Baruku wipe, Sọ fun wa nisisiyi, bawo ni iwọ ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi lati ẹnu rẹ̀?
18Baruku si da wọn lohùn pe; Lati ẹnu rẹ̀ li o si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun mi, emi si fi tadawa kọ wọn sinu iwe na.
19Nigbana ni awọn ijoye sọ fun Baruku pe, Lọ, fi ara rẹ pamọ, iwọ ati Jeremiah; má si jẹ ki ẹnikan mọ̀ ibi ti ẹnyin wà.
Ọba Sun Ìwé Àkọsílẹ̀ Náà Níná
20Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba.
21Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba.
22Ọba si ngbe ile igba-otutu li oṣu kẹsan: ina si njo niwaju rẹ̀ ninu idana.
23O si ṣe, nigbati Jehudu ti kà ewe mẹta tabi mẹrin, ọba fi ọbẹ ke iwe na, o si sọ ọ sinu iná ti o wà ninu idaná, titi gbogbo iwe-kiká na fi joná ninu iná ti o wà lori idaná.
24Sibẹ nwọn kò warìri, nwọn kò si fa aṣọ wọn ya, ani ọba, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi.
25Ṣugbọn Elnatani ati Delaiah ati Gemariah bẹbẹ lọdọ ọba ki o máṣe fi iwe-kiká na joná, kò si fẹ igbọ́ ti wọn.
26Ṣugbọn ọba paṣẹ fun Jerameeli, ọmọ Hameleki, ati Seraiah, ọmọ Asraeli, ati Ṣelemiah, ọmọ Abdeeli, lati mu Baruku akọwe, ati Jeremiah woli: ṣugbọn Oluwa fi wọn pamọ.
Jeremiah kọ Ìwé Mìíràn
27Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá, lẹhin ti ọba ti fi iwe-kiká na ati ọ̀rọ ti Baruku kọ lati ẹnu Jeremiah wá joná, wipe,
28Tun mu iwe kiká miran, ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ iṣaju sinu rẹ̀ ti o wà ninu iwe-kiká ekini, ti Jehoiakimu, ọba Juda, ti fi joná.
29Iwọ o si sọ niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti fi iwe-kiká yi joná o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi kọwe sinu rẹ̀, pe: Lõtọ ọba Babeli yio wá yio si pa ilẹ yi run, yio si pa enia ati ẹran run kuro ninu rẹ̀?
30Nitorina bayi li Oluwa wi niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, On kì yio ni ẹniti yio joko lori itẹ Dafidi: a o si sọ okú rẹ̀ nù fun oru li ọsan, ati fun otutu li õru.
31Emi o si jẹ on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ niya, nitori aiṣedede wọn; emi o si mu wá sori wọn, ati sori awọn olugbe Jerusalemu, ati sori awọn ọkunrin Juda, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn, ṣugbọn nwọn kò gbọ́.
32Nigbana ni Jeremiah mu iwe-kiká miran, o si fi i fun Baruku, akọwe, ọmọ Neriah; ẹniti o kọwe sinu rẹ̀ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ iwe ti Jehoiakimu, ọba Juda ti sun ninu iná: a si fi ọ̀rọ pupọ bi iru eyi kún ọ̀rọ iwe na pẹlu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 36: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.