Jer 18
18
Jeremiah nílé Amọ̀kòkò
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ̀ Oluwa wipe,
2Dide, sọkalẹ lọ si ile amọkoko, nibẹ li emi o mu ọ gbọ́ ọ̀rọ mi.
3Mo si sọkalẹ lọ si ile amọkoko, sa wò o, o mọ iṣẹ kan lori kẹ̀kẹ.
4Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ.
5Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,
6Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.
7Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run.
8Bi orilẹ-ède na ti mo ti sọ ọ̀rọ si ba yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀, emi o yi ọkàn mi pada niti ibi ti emi ti rò lati ṣe si wọn.
9Ati lojukanna ti emi sọ ọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan, lati tẹ̀ ẹ do ati lati gbìn i.
10Bi o ba ṣe ibi niwaju mi, ti kò si gbà ohùn mi gbọ́: nigbana ni emi o yi ọkàn mi pada niti rere, eyiti mo wi pe, emi o ṣe fun wọn.
11Njẹ nisisiyi, sa sọ fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi npete ibi si nyin, emi si nṣe ipinnu kan si nyin, si yipada, olukuluku kuro ninu ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun ọ̀na ati iṣe nyin ṣe rere.
12Nwọn si wipe: Lasan ni: nitori awa o rìn nipa ipinnu wa, olukuluku yio si huwa agidi ọkàn buburu rẹ̀.
Àwọn Eniyan náà kọ OLUWA Sílẹ̀
13Nitorina bayi li Oluwa wí, Ẹ sa bère ninu awọn orilẹ-ède, tani gbọ́ iru ohun wọnni: wundia Israeli ti ṣe ohun kan ti o buru jayi.
14Omi ojo-didì Lebanoni yio ha dá lati ma ṣàn lati apata oko? tabi odò ti o jina, ti o tutu, ti o nṣan, yio ha gbẹ bi?
15Nitoripe awọn enia mi gbàgbe mi, nwọn ti sun turari fun ohun asan, nwọn si ti mu ki nwọn ki o ṣubu loju ọ̀na wọn, ni ipa igbãni; lati rìn ni ipa ti a kò tẹ́.
16Lati sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹ̀gan lailai; olukuluku ẹniti o ba kọja nibẹ, yio dãmu yio mì ori rẹ̀ si i.
17Emi o tú wọn ka gẹgẹ bi ẹ̀fufu ila-õrùn niwaju ọta wọn; emi o kọ ẹ̀hin mi si wọn, kì yio ṣe oju mi, ni ọjọ iparun wọn.
Wọ́n Gbìmọ̀ Ibi sí Jeremiah
18Nigbana ni nwọn wipe, Wá, ẹ jẹ ki a pinnu ìwa ibi si Jeremiah, nitori ofin kì yio ṣegbe lọwọ alufa, tabi igbimọ lọwọ ọlọgbọ́n, tabi ọ̀rọ lọwọ woli: ẹ wá, ẹ jẹ ki a fi ahọn wa lù u, ki a má si kiyesi ohun kan ninu ọ̀rọ rẹ̀.
19Kiyesi mi, Oluwa, ki o si gbọ́ ohùn awọn ti nni mi lara.
20A ha le fi ibi san rere? nitori nwọn ti wà iho fun ẹmi mi. Ranti pe emi ti duro niwaju rẹ lati sọ ohun rere nipa ti wọn, ati lati yi ibinu rẹ kuro lọdọ wọn.
21Nitorina, fi awọn ọmọ wọn fun ìyan, ki o si fi idà pa wọn, jẹ ki aya wọn ki o di alailọmọ ati opó: ki a si fi ìka pa awọn ọkunrin wọn, jẹ ki a fi idà pa awọn ọdọmọde wọn li ogun.
22Jẹ ki a gbọ́ igbe lati ilẹ wọn, nigbati iwọ o mu ẹgbẹ kan wá lojiji sori wọn: nitori nwọn ti wà ihò lati mu mi, nwọn si dẹ okùn fun ẹsẹ mi.
23Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ mọ̀ gbogbo igbimọ wọn si mi lati pa mi, máṣe bò ẹbi wọn mọlẹ, bẹ̃ni ki iwọ máṣe pa ẹṣẹ wọn rẹ́ kuro niwaju rẹ, jẹ ki nwọn ki o ṣubu niwaju rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe si wọn ni ọjọ ibinu rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.