Gẹn 37:5-7

Gẹn 37:5-7 YBCV

Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i. O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá. Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi.