Esek 18
18
1Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2Kini ẹnyin rò ti ẹnyin fi npowe yi niti ilẹ Israeli, pe, Awọn baba ti jẹ eso àjara kíkan, ehin awọn ọmọ si kan.
3Oluwa Ọlọrun wipe, bi mo ti wà, ẹnyin kì yio ri àye lati powe yi mọ ni ilẹ Israeli.
4Kiye si i, gbogbo ọkàn ni t'emi; gẹgẹ bi ọkàn baba ti jẹ t'emi, bẹ̃ni t'emi ni ọkàn ọmọ pẹlu; ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú.
5Ṣugbọn bi enia kan ba ṣe olõtọ, ti o si ṣe eyiti o tọ ati eyiti o yẹ,
6Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀.
7Ti kò si ni ẹnikan lara, ṣugbọn ti o ti fi ohun ògo onigbèse fun u, ti kò fi agbara kó ẹnikẹni, ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹwu bo ẹni-ihoho.
8Ẹniti kò fi fun ni lati gba ẹdá, bẹ̃ni kò gba elékele, ti o ti fa ọwọ́ rẹ̀ kuro ninu aiṣedẽde, ti o ti mu idajọ otitọ ṣẹ lãrin ọkunrin ati ọkunrin,
9Ti o ti rìn ninu aṣẹ mi, ti o si ti pa idajọ mi mọ, lati hùwa titọ́; on ṣe olõtọ, yiyè ni yio yè, ni Oluwa Ọlọrun wi.
10Bi o ba bi ọmọkunrin kan ti iṣe ọlọṣà, oluta ẹ̀jẹ silẹ, ti o si nṣe ohun ti o jọ ọkan ninu nkan wọnyi si arakunrin rẹ̀.
11Ti kò si ṣe ọkan ninu gbogbo iṣẹ wọnni, ṣugbọn ti o tilẹ ti jẹun lori oke, ti o si ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,
12Ti o ti ni talaka ati alaini lara; ti o ti fi agbara koni, ti kò mu ohun ògo pada, ti o ti gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa, ti o ti ṣe ohun irira,
13Ti o ti fi fun ni lati gba ẹdá, ti o si ti gba èle: on o ha yè bẹ̃? on ki yio yè: on ti ṣe gbogbo ohun irira wọnyi; kikú ni yio kú: ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.
14Si kiye si i, bi o ba bi ọmọkunrin ti o ri gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si bẹ̀ru, ti kò si ṣe iru rẹ̀,
15Ti kò si jẹun lori oke, ti kò gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa ile Israeli, ti kò ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,
16Ti kò ni ẹnikan lara, ti kò dá ohun ògo duro, ti kò fi agbara koni, ṣugbọn ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹ̀wu bo ẹni-ihoho,
17Ti o ti mu ọwọ́ rẹ̀ kuro lara ẹni-inilara, ti kò ti gba ẹdá tabi elé ti o ti mu idajọ mi ṣẹ, ti o ti rìn ninu aṣẹ mi; on kì yio kú nitori aiṣedẽde baba rẹ̀, yiyè ni yio yè.
18Bi o ṣe ti baba rẹ̀, nitoripe o fi ikà ninilara, ti o fi agbara ko arakunrin rẹ̀; ti o ṣe eyiti kò dara lãrin enia rẹ̀, kiye si i, on o tilẹ kú ninu aiṣedẽde rẹ̀.
19Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẽṣe? ọmọ kò ha ru aiṣedẽde baba? Nigbati ọmọ ti ṣe eyiti o tọ́ ati eyiti o yẹ, ti o si ti pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ti ṣe wọn, yiyè ni yio yè.
20Ọkàn ti o ba ṣẹ̀, on o kú. Ọmọ kì yio rù aiṣedẽde baba, bẹ̃ni baba kì yio rù aiṣedẽde ọmọ: ododo olododo yio wà lori rẹ̀, ìwa buburu enia buburu yio si wà lori rẹ̀.
21Ṣugbọn bi enia buburu yio ba yipada kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ti o si pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ṣe eyi ti o tọ́, ati eyiti o yẹ, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.
22Gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, a kì yio ranti wọn si i: ninu ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni on o yè.
23Emi ha ni inu-didùn rara pe ki enia buburu ki o kú? ni Oluwa Ọlọrun wi: kò ṣepe ki o yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, ki o si yè?
24Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yè? gbogbo ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni a kì yio ranti: ninu irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ninu wọn ni yio kú.
25Ṣugbọn ẹnyin wipe, ọ̀na Oluwa kò gún. Gbọ́ nisisiyi, iwọ ile Israeli; ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?
26Nigbati olododo kan ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedẽde, ti o si kú ninu wọn; nitori aiṣedẽde rẹ̀ ti o ti ṣe ni yio kú.
27Ẹwẹ, nigbati enia buburu ba yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si ṣe eyiti o tọ́, ati eyiti o yẹ, on o gba ọkàn rẹ̀ là lãye.
28Nitoripe o bẹ̀ru o si yipada kuro ninu gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.
29Ṣugbọn ile Israeli wipe, Ọ̀na Oluwa kò gún. Ile Israeli, ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?
30Nitorina emi o dá nyin lẹjọ, ile Israeli, olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ẹ yipada, ki ẹ si yi kuro ninu gbogbo irekọja nyin; bẹ̃ni aiṣedẽde kì yio jẹ iparun nyin.
31Ẹ ta gbogbo irekọja nyin nù kuro lọdọ nyin, nipa eyiti ẹnyin fi rekọja; ẹ si dá ọkàn titun ati ẹmi titun fun ara nyin: nitori kini ẹnyin o ṣe kú, ile Israeli?
32Nitoripe emi kò ni inu didùn si ikú ẹniti o kú, ni Oluwa Ọlọrun wi: nitorina ẹ yi ara nyin pada, ki ẹ si yè.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.