Deu 12
12
Ibi Ìjọ́sìn Kanṣoṣo Náà
1WỌNYI ni ìlana ati idajọ, ti ẹnyin o ma kiyesi lati ma ṣe ni ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ fi fun ọ lati ní, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà lori ilẹ-aiye.
2Ki ẹnyin ki o run ibi gbogbo wọnni patapata, nibiti awọn orilẹ-ède nì, ti ẹnyin o gbà, nsìn oriṣa wọn, lori òke giga, ati lori òke kekeké, ati labẹ igi tutù gbogbo:
3Ki ẹnyin ki o si wó pẹpẹ wọn, ki ẹ si bì ọwọ̀n wọn ṣubu, ki ẹ si fi iná kun igbo oriṣa wọn; ki ẹnyin ki o si ke ere fifin wọn lulẹ, ki ẹ si run orukọ wọn kuro ni ibẹ na.
4Ẹnyin kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin.
5Ṣugbọn ibi ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn ninu gbogbo ẹ̀ya nyin lati fi orukọ rẹ̀ si, ani ibujoko rẹ̀ li ẹnyin o ma wálọ, ati nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma wá:
6Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o ma mú ẹbọ sisun nyin wá, ati ẹbọ nyin, ati idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ifẹ́-atinuwa nyin, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran nyin ati ti agbo-ẹran nyin:
7Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ma jẹ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ ninu ohun gbogbo ti ẹnyin fi ọwọ́ nyin lé, ẹnyin ati awọn ara ile nyin, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún u fun ọ.
8Ki ẹnyin ki o máṣe ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awa nṣe nihin li oni, olukuluku enia ohun ti o tọ́ li oju ara rẹ̀:
9Nitoripe ẹnyin kò sá ti idé ibi-isimi, ati ilẹ iní, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin.
10Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gòke Jordani, ti ẹnyin si joko ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin ni iní, ti o ba si fun nyin ni isimi kuro lọwọ awọn ọtá nyin gbogbo yiká, ti ẹnyin si joko li alafia:
11Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA.
12Ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin, ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode nyin, nitori on kò ní ipín tabi iní pẹlu nyin.
13Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe ru ẹbọ sisun rẹ ni ibi gbogbo ti iwọ ba ri:
14Bikoṣe ni ibi ti OLUWA yio yàn ninu ọkan ninu awọn ẹ̀ya rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ.
15Ṣugbọn ki iwọ ki o ma pa, ki o si ma jẹ ẹran ninu ibode rẹ gbogbo, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ ni ki o ma jẹ ninu rẹ̀, bi esuro, ati bi agbọnrin.
16Kìki ẹ̀jẹ li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; lori ilẹ ni ki ẹ dà a si bi omi.
17Ki iwọ ki o máṣe jẹ idamẹwa ọkà rẹ ninu ibode rẹ, tabi ti ọti-waini rẹ, tabi ti oróro rẹ, tabi ti akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, tabi ti agbo-ẹran rẹ, tabi ti ẹjẹ́ rẹ ti iwọ jẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwa rẹ, tabi ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ rẹ:
18Bikoṣe ki iwọ ki o jẹ wọn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ: ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ninu ohun gbogbo ti iwọ fi ọwọ́ rẹ le.
19Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe kọ̀ ọmọ Lefi silẹ ni gbogbo ọjọ́ rẹ lori ilẹ.
20Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ti iwọ ba si wipe, Emi o jẹ ẹran, nitoriti ọkàn rẹ nfẹ́ ẹran ijẹ; ki iwọ ki o ma jẹ ẹran, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ́.
21Bi o ba ṣepe, ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ ba yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si, ba jìna jù fun ọ, njẹ ki iwọ ki o pa ninu ọwọ́-ẹran rẹ ati ninu agbo-ẹran rẹ, ti OLUWA fi fun ọ, bi emi ti fi aṣẹ fun o, ki iwọ ki o si ma jẹ ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́ ninu ibode rẹ.
22Ani bi ã ti ijẹ esuro, ati agbọnrin, bẹ̃ni ki iwọ ki o ma jẹ wọn: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ yio jẹ ninu wọn bakanna.
23Kìki ki o ṣọ́ ara rẹ gidigidi ki iwọ ki o máṣe jẹ ẹ̀jẹ: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi; iwọ kò si gbọdọ jẹ ẹmi pẹlu ẹran.
24Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; iwọ o dà a silẹ bi omi.
25Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; ki o le ma dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.
26Kìki ohun mimọ́ rẹ ti iwọ ní, ati ẹjẹ́ rẹ ni ki iwọ ki o mú, ki o si lọ si ibi ti OLUWA yio yàn:
27Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun rẹ, ẹran ati ẹ̀jẹ na, lori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ati ẹ̀jẹ ẹbọ rẹ ni ki a dà sori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma jẹ ẹran na.
28Kiyesara ki o si ma gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti mo palaṣẹ fun ọ, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ lailai, nigbati iwọ ba ṣe eyiti o dara ti o si tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.
29Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro niwaju rẹ, nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà wọn, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilẹ wọn;
30Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ má ba bọ́ si idẹkùn ati tẹle wọn lẹhin, lẹhin igbati a ti run wọn kuro niwaju rẹ; ki iwọ ki o má si bère oriṣa wọn, wipe, Bawo li awọn orilẹ-ède wọnyi ti nsìn oriṣa wọn? emi o si ṣe bẹ̃ pẹlu.
31Iwọ kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe gbogbo ohun irira si OLUWA, ti on korira ni nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; nitoripe awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin wọn pẹlu ni nwọn nsun ninu iná fun oriṣa wọn.
32Ohunkohun ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin, ẹ ma kiyesi lati ṣe e: iwọ kò gbọdọ fikún u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 12: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.