II. A. Ọba 9
9
A fi Òróró Yan Jehu ní Ọba Israẹli
1ELIṢA woli si pè ọkan ninu awọn ọmọ woli, o si wi fun u pe, Dì amurè ẹ̀gbẹ rẹ, ki o si mu igò ororo yi lọwọ rẹ, ki o si lọ si Ramoti-Gileadi:
2Nigbati iwọ ba si de ibẹ, ki iwọ ki o wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi li awari nibẹ, ki o si wọle, ki o si mu u ki o dide kuro lãrin awọn arakunrin rẹ̀, ki o si mu u lọ si yàra inu ile lọhun;
3Ki o si mu igò ororo na, ki o si tú u si ori rẹ̀, ki o si wipe, Bayi li Oluwa wipe, Emi fi ororo yàn ọ li ọba li ori Israeli. Si ṣi ilẹkun, ki o si sá, má si ṣe duro.
4Bẹ̃ni ọdọmọkunrin na, ani ọdọmọkunrin woli na, lọ si Ramoti-Gileadi.
5Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun.
6On si dide, o si wọ̀ inu ile: o si tú ororo na si i li ori, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia Oluwa, lori Israeli.
7Iwọ o si kọlù ile Ahabu oluwa rẹ, ki emi o le gbẹsan ẹjẹ awọn woli iranṣẹ mi, ati ẹ̀jẹ gbogbo awọn iranṣẹ Oluwa lọwọ Jesebeli.
8Nitori gbogbo ile Ahabu ni yio ṣegbé: emi o si ké gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Ahabu ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli:
9Emi o si ṣe ile Ahabu bi ile Jeroboamu ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa ọmọ Ahijah;
10Awọn aja yio si jẹ Jesebeli ni oko Jesreeli, kì yio si ẹniti yio sinkú rẹ̀. O si ṣi ilẹkùn, o si sá lọ.
11Nigbana ni Jehu jade tọ̀ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀: ẹnikan si wi fun u pe, Alafia kọ́? nitori kini aṣiwère yi ṣe tọ̀ ọ wá? On si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ọkunrin na ati ọ̀rọ rẹ̀.
12Nwọn si wipe, Eke; sọ fun wa wayi. On si wipe, Bayi bayi li o sọ fun mi wipe, Bayi ni Oluwa wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori Israeli.
13Nigbana ni nwọn yára, olukulùku si mu agbáda rẹ̀, o si fi i si abẹ rẹ̀ lori atẹ̀gun, nwọn si fun ipè wipe, Jehu jọba.
Wọ́n pa Joramu, Ọba Israẹli
14Bẹ̃ni Jehu ọmọ Jehoṣafati ọmọ Nimṣi ṣotẹ si Joramu. (Njẹ Joramu ti nṣọ Ramoti-Gileadi, on, ati gbogbo Israeli, nitoriti Hasaeli ọba Siria:
15Ṣugbọn Joramu ọba ti pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ṣa a, nigbati o ba Hasaeli ọba Siria jà.) Jehu si wipe, Bi o ba ṣe ifẹ inu nyin ni, ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ki o jade lọ, tabi ki o yọ́ lọ kuro ni ilu lati lọ isọ ni Jesreeli.
16Bẹ̃ni Jehu gùn kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli; nitori Joramu dùbulẹ nibẹ. Ahasiah ọba Juda si sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu.
17Olùṣọ kan si duro ni ile iṣọ ni Jesreeli, o si ri ẹgbẹ́ Jehu bi o ti mbọ̀ wá, o si wipe, Mo ri ẹgbẹ́ kan. Joramu si wipe, Mu ẹlẹṣin kan, ki o si ranṣẹ lọ ipade wọn, ki o si wipe, Alafia kọ́?
18Ẹnikan si lọ lori ẹṣin lati pade rẹ̀, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ pe, Iranṣẹ na de ọdọ wọn, ṣugbọn kò si tun pada wá mọ.
19O si rán ekeji jade lori ẹṣin on si tọ̀ wọn wá, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si dahùn wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi.
20Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan.
21Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli.
22O si ṣe, nigbati Joramu ri Jehu li o wipe, Jehu, Alafia kọ́? On si wipe, Alafia kini, niwọ̀nbi iwà-agbère Jesebeli ìya rẹ ati iṣe ajẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tobẹ̃?
23Joramu si yi ọwọ rẹ̀ pada, o si sá, o si wi fun Ahasiah pe, Ọtẹ̀ de, Ahasiah.
24Jehu si fi gbogbo agbara rẹ̀ fà ọrun o si ta Joramu lãrin apa rẹ̀ mejeji, ọfà na si gbà ọkàn rẹ̀ jade, o si dojubolẹ ninu kẹkẹ́ rẹ̀.
25Nigbana ni Jehu sọ fun Bidkari balogun rẹ̀, pe, Gbe e ki o si sọ ọ si oko Naboti ara Jesreeli: sa ranti bi igbati temi tirẹ jumọ ngùn kẹkẹ́ lẹhin Ahabu baba rẹ̀, Oluwa ti sọ ọ̀rọ-ìmọ yi sori rẹ̀.
26Nitõtọ li ana emi ti ri ẹ̀jẹ Naboti ati ẹ̀jẹ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, li Oluwa wi; emi o si san a fun ọ ni oko yi, li Oluwa wi. Njẹ nitorina, ẹ mu u, ki ẹ si sọ ọ sinu oko na gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
A Pa Ahasaya Ọba Juda
27Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ.
28Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.
29Li ọdun ikọkanla Joramu ọmọ Ahabu ni Ahasiah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda.
A pa Jesebẹli Ayaba
30Nigbati Jehu si de Jesreeli, Jesebeli gbọ́; on si le tìrõ, o si ta ori rẹ̀, o si yọju wode ni fèrese.
31Bi Jehu si ti ngbà ẹnu-ọ̀na wọle, o wipe, Simri ti o pa oluwa rẹ̀ ri alafia bi?
32On si gbé oju rẹ̀ si òke fèrese, o si wipe, Tani nṣe ti emi? tani? Awọn iwẹ̀fa meji bi mẹta si yọju si i lode.
33On si wipe, Ẹ tari rẹ̀ silẹ. Nwọn si tari rẹ̀ silẹ: diẹ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ si ta si ara ogiri, ati si ara awọn ẹṣin: on si tẹ̀ ẹ mọlẹ.
34Nigbati o si wọle, o jẹ, o si mu, o si wipe, Ẹ lọ iwò obinrin egun yi wàyi, ki ẹ si sìn i: nitori ọmọbinrin ọba li on iṣe.
35Nwọn si lọ isin i; ṣugbọn nwọn kó ri ninu rẹ̀ jù agbari, ati ẹsẹ̀ ati atẹ́lẹwọ rẹ̀ lọ.
36Nitorina nwọn si tun pada wá, nwọn si sọ fun u. On si wipe, Eyi li ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀ ara Tiṣbi wipe, Ni oko Jesreeli li awọn aja yio jẹ ẹran-ara Jesebeli:
37Okú Jesebeli yio si dàbi imí ni igbẹ́, ni oko Jesreeli; tobẹ̃ ti nwọn kì yio wipe, Jesebeli li eyi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.