ORIN DAFIDI 72:1-14

ORIN DAFIDI 72:1-14 YCE

Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́; kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ. Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ, kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́; kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia, kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké. Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ; kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀; kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú. Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ. Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti gé àní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀. Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀; kí alaafia ó gbilẹ̀ títí tí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́. Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun, ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un; àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogbo yóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un; àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀; a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀, ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka, a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá, ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.