ORIN DAFIDI 57:7-11

ORIN DAFIDI 57:7-11 YCE

Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun, ọkàn mi dúró ṣinṣin! N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu, èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu. OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan; n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.