MATIU 26:55-75

MATIU 26:55-75 YCE

Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà! Ṣugbọn gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ àwọn wolii lè ṣẹ ni.” Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ. Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí. Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á. Ṣugbọn wọn kò rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọpọ ni àwọn ẹlẹ́rìí-èké tí wọ́n yọjú. Ní ìgbẹ̀yìn àwọn meji kan wá. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó Tẹmpili Ọlọrun yìí, kí n sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.’ ” Olórí Alufaa bá dìde, ó ní, “O kò fèsì rárá? Àbí o kò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ pé o wí?” Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnu ara rẹ ni o fi sọ ọ́; ṣugbọn mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.” Olórí Alufaa bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “O sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àfojúdi tí ó sọ sí Ọlọrun nisinsinyii. Kí ni ẹ rò?” Wọ́n dáhùn pé, “Ikú ni ó tọ́ sí i.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lójú, wọ́n ń sọ ọ́ lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n ń gbá a létí. Wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ, Mesaya, sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa!” Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.” Ṣugbọn Peteru sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní, “N kò mọ ohun tí ò ń sọ.” Bí ó ti ń lọ sí ẹnu ọ̀nà, iranṣẹbinrin mìíràn tún rí i, ó bá sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.” Peteru tún sẹ́, ó búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.” Ó ṣe díẹ̀ si, àwọn tí ó dúró níbẹ̀ tọ Peteru lọ, wọ́n sọ fún un pé, “Òtítọ́ ni pé ọ̀kan ninu wọn ni ìwọ náà í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ fihàn bẹ́ẹ̀!” Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó tún ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.” Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kọ. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ, pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ó bá bọ́ sóde, ó sọkún gidigidi.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ