DANIẸLI 7:25-27

DANIẸLI 7:25-27 YCE

Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀. Ṣugbọn ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, a óo gba àṣẹ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, a óo sì pa á run patapata. A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’