TẸSALONIKA KINNI 2:3-8

TẸSALONIKA KINNI 2:3-8 YCE

Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti kà wá yẹ, tí ó fi iṣẹ́ ìyìn rere lé wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe láti tẹ́ eniyan lọ́rùn, bíkòṣe pé láti tẹ́ Ọlọrun tí ó mọ ọkàn wa lọ́rùn. Nítorí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, a kò wá pọ́n ẹnikẹ́ni, a kò sì wá ṣe àṣehàn bí ẹni tí ìwọ̀ra wà lọ́kàn rẹ̀. A fi Ọlọrun ṣe ẹlẹ́rìí! Bẹ́ẹ̀ ni a kò wá ìyìn eniyan, ìbáà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín, tabi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà ní ipò láti gba ìyìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi. Ṣugbọn à ń ṣe jẹ́jẹ́ láàrin yín, àní gẹ́gẹ́ bí obinrin alágbàtọ́ tíí ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ tí ó ń tọ́jú. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa fà sọ́dọ̀ yín; kì í ṣe ìyìn rere nìkan ni a fẹ́ fun yín, ṣugbọn ó dàbí ẹni pé kí á gbé gbogbo ara wa fun yín, nítorí ẹ ṣọ̀wọ́n fún wa.