Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 6:13
Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́
Ọjọ́ márùn
O ti pinnu láti tẹ̀lé Jésù, kí lo wá ku? Ètò yìí kì ń ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa gbogbo nǹkan tó níṣe pẹ̀lú ìpinnu náà, ṣùgbọ́n yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́.
Awọn adura Jesu
Ọjọ marun
A mọ pataki pataki ti ibaraẹnisọrọ ni awọn ibasepọ, ati ibasepo wa pẹlu Ọlọhun kii ṣe iyatọ. Ọlọrun nfẹ fun wa lati ba a sọrọ pẹlu adura-ibawi ti Ọmọ rẹ, Jesu, ṣe. Ninu eto yii, iwọ yoo kọ ẹkọ lati apẹẹrẹ Jesu, ao si ni ẹsun lati lọ kuro ninu ijabọ igbesi aye ati iriri fun ara rẹ agbara ati adura itọnisọna pese.
Ẹ̀jẹ́ Náà
Ọjọ́ mẹ́fà
Nínú Ètò Bíbélì Life.Church yí, àwọn l'ọkọ l'áya (tọkọtaya) mẹ́fà kọ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó tí wọn kò ní àǹfààní láti kà níwájú pẹpẹ. Àwọn májẹ̀mú ìpalémọ, oun-tó-ṣe-pàtàkì, ìlépa, àjọṣepọ̀, àìlábàwón, àdúrà ni májẹ̀mú tí ó máa ń mú ìgbéyàwó lọ létòletò kọjá àkókò adùn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Bóyá o ti gbéyàwó tàbí o kò ì tí gbéyàwó, àkókò ti tó láti dá májẹ̀mú
Lilépa Káróòtì
Ọjọ́ méje
Gbogbo wá ló ǹ lépa nǹkan kan.O sábà máa ń jẹ́ nǹkan tí kò sí lárọ́wọ́tó bíi—iṣẹ́ tó dára, ilé tó tún dára,ìdílé pípé, àfọwọ́sí àwọn ẹlòmíràn. Àmó ńjẹ́ èyí kì í múni se àárẹ̀? See kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára ni? Ṣe ìwádìí nínú ètò Bíbélì titun tí Life.Church, tí ń tè lé onírúurú ìwàásù Pastor Craig Groeschel nípa, lílépa kárọ́ọ̀tì.
Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwu
Ọjọ́ Méje
Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.
Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtì
Ọjọ́ Méje
Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.
Ìjọba Dé
Ojọ́ Márùn-din-logun
A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.
Àdúrà
Ọjọ́ Mọ́kànlé-Lógún
Kọ́ bí ó ṣe dára jùlọ láti gbàdúrà, láti inú ádùrá àwọn olódodo àti láti àwọn ọ̀rọ̀ Jésù fún rara Rẹ̀. Wá ìwúrí láti máa mú àwọn ìbéèrè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run l'ójoojúmọ́, pẹ̀lú ìtẹramọ́ṣẹ́ àti sùúrù. Ṣ'àwárí àwọn àpẹẹrẹ ádùrá òfo, òdodo ti ara ẹni, èyí tí ó ṣe déédé sí àwọn ádùrá mímọ́ ti àwọn tí ó ní ọkàn mímọ́. Gbàdúrà nígbà gbogbo.