LUKU 14:28-30
LUKU 14:28-30 YCE
“Nítorí ta ni ninu yín tí yóo fẹ́ kọ́ ilé ńlá kan, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye tí yóo ná òun, kí ó mọ̀ bí òun bá ní ohun tí òun yóo fi parí rẹ̀? Kí ó má wá jẹ́ pé yóo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ tán, kò ní lè parí rẹ̀ mọ́. Gbogbo àwọn tí ó bá rí i yóo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọkunrin yìí bẹ̀rẹ̀ ilé, kò lè parí rẹ̀!’