1
JẸNẸSISI 32:28
Yoruba Bible
Ọkunrin náà bá dáhùn pé, “A kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni a óo máa pè ọ́, nítorí pé o ti bá Ọlọrun ati eniyan wọ ìjàkadì, o sì ti ṣẹgun.”
เปรียบเทียบ
สำรวจ JẸNẸSISI 32:28
2
JẸNẸSISI 32:26
Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.”
สำรวจ JẸNẸSISI 32:26
3
JẸNẸSISI 32:24
Ó wá ku Jakọbu nìkan, ọkunrin kan bá a wọ ìjàkadì títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ keji.
สำรวจ JẸNẸSISI 32:24
4
JẸNẸSISI 32:30
Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.”
สำรวจ JẸNẸSISI 32:30
5
JẸNẸSISI 32:25
Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì.
สำรวจ JẸNẸSISI 32:25
6
JẸNẸSISI 32:27
Ọkunrin náà bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Jakọbu dáhùn pé, “Jakọbu ni.”
สำรวจ JẸNẸSISI 32:27
7
JẸNẸSISI 32:29
Jakọbu bá bẹ̀ ẹ́, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣugbọn ó dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí o fi ń bèèrè orúkọ mi?” Ó bá súre fún Jakọbu níbẹ̀.
สำรวจ JẸNẸSISI 32:29
8
JẸNẸSISI 32:10
N kò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí tí ó kéré jùlọ ninu ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀, ati òdodo tí o ti fihan èmi iranṣẹ rẹ, nítorí ọ̀pá lásán ni mo mú lọ́wọ́ nígbà tí mo gòkè odò Jọdani, ṣugbọn nisinsinyii, mo ti di ẹgbẹ́ ogun ńlá meji.
สำรวจ JẸNẸSISI 32:10
9
JẸNẸSISI 32:32
Nítorí náà, títí di òní, àwọn ọmọ Israẹli kì í jẹ iṣan tí ó bo ihò itan níbi tí itan ti sopọ̀ mọ́ ìbàdí, nítorí pé ihò itan Jakọbu ni ọkunrin náà fọwọ́ kàn, orí iṣan tí ó so ó pọ̀ mọ́ ìbàdí.
สำรวจ JẸNẸSISI 32:32
10
JẸNẸSISI 32:9
Jakọbu bá gbadura báyìí pé, “Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, Ọlọrun tí ó wí fún mi pé, ‘Pada sí ilẹ̀ rẹ ati sí ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, n óo sì ṣe ọ́ níre.’
สำรวจ JẸNẸSISI 32:9
11
JẸNẸSISI 32:11
Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn.
สำรวจ JẸNẸSISI 32:11
หน้าหลัก
พระคัมภีร์
แผนการอ่าน
วิดีโอ