Luk 4:9-12
Luk 4:9-12 YBCV
O si mu u lọ si Jerusalemu, o si gbé e le ṣonṣo tẹmpili, o si wi fun u pe, Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ lati ihinyi lọ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, lati ma ṣe itọju rẹ: Ati pe li ọwọ́ wọn ni nwọn o gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. Jesu si dahùn o wi fun u pe, A ti sọ pe, Iwọ kò gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.