1
Gẹnẹsisi 15:6
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Abramu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.
Bandingkan
Selidiki Gẹnẹsisi 15:6
2
Gẹnẹsisi 15:1
Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Abramu wá lójú ìran pé: “Abramu má ṣe bẹ̀rù, Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”
Selidiki Gẹnẹsisi 15:1
3
Gẹnẹsisi 15:5
OLúWA sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”
Selidiki Gẹnẹsisi 15:5
4
Gẹnẹsisi 15:4
Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”
Selidiki Gẹnẹsisi 15:4
5
Gẹnẹsisi 15:13
Nígbà náà ni OLúWA wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400).
Selidiki Gẹnẹsisi 15:13
6
Gẹnẹsisi 15:2
Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “OLúWA Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,”
Selidiki Gẹnẹsisi 15:2
7
Gẹnẹsisi 15:18
Ní ọjọ́ náà gan an ni OLúWA dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate
Selidiki Gẹnẹsisi 15:18
8
Gẹnẹsisi 15:16
Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”
Selidiki Gẹnẹsisi 15:16
Halaman Utama
Alkitab
Pelan
Video