1
Gẹnẹsisi 12:2-3
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí. Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.”
Bandingkan
Selidiki Gẹnẹsisi 12:2-3
2
Gẹnẹsisi 12:1
OLúWA sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.
Selidiki Gẹnẹsisi 12:1
3
Gẹnẹsisi 12:4
Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí OLúWA ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani.
Selidiki Gẹnẹsisi 12:4
4
Gẹnẹsisi 12:7
OLúWA sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún OLúWA tí ó fi ara hàn án.
Selidiki Gẹnẹsisi 12:7
Halaman Utama
Alkitab
Pelan
Video