1
JẸNẸSISI 1:26-27
Yoruba Bible
Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn.
Compare
Explore JẸNẸSISI 1:26-27
2
JẸNẸSISI 1:28
Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”
Explore JẸNẸSISI 1:28
3
JẸNẸSISI 1:1
Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé
Explore JẸNẸSISI 1:1
4
JẸNẸSISI 1:2
ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi.
Explore JẸNẸSISI 1:2
5
JẸNẸSISI 1:3
Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà.
Explore JẸNẸSISI 1:3
6
JẸNẸSISI 1:31
Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa.
Explore JẸNẸSISI 1:31
7
JẸNẸSISI 1:4
Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn.
Explore JẸNẸSISI 1:4
8
JẸNẸSISI 1:29
Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ.
Explore JẸNẸSISI 1:29
9
JẸNẸSISI 1:5
Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni.
Explore JẸNẸSISI 1:5
10
JẸNẸSISI 1:6
Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.
Explore JẸNẸSISI 1:6
11
JẸNẸSISI 1:30
Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Explore JẸNẸSISI 1:30
12
JẸNẸSISI 1:14
Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn
Explore JẸNẸSISI 1:14
13
JẸNẸSISI 1:11
Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Explore JẸNẸSISI 1:11
14
JẸNẸSISI 1:7
Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Explore JẸNẸSISI 1:7
15
JẸNẸSISI 1:12
Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.
Explore JẸNẸSISI 1:12
16
JẸNẸSISI 1:16
Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu.
Explore JẸNẸSISI 1:16
17
JẸNẸSISI 1:9-10
Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára.
Explore JẸNẸSISI 1:9-10
18
JẸNẸSISI 1:22
Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.”
Explore JẸNẸSISI 1:22
19
JẸNẸSISI 1:24
Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Explore JẸNẸSISI 1:24
20
JẸNẸSISI 1:20
Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ.
Explore JẸNẸSISI 1:20
21
JẸNẸSISI 1:25
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.
Explore JẸNẸSISI 1:25
ಮುಖಪುಟ
ಬೈಬಲ್
ಯೋಜನೆಗಳು
ವೀಡಿಯೊಗಳು