1
Gẹn 22:14
Bibeli Mimọ
Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i.
Összehasonlít
Fedezd fel: Gẹn 22:14
2
Gẹn 22:2
O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ.
Fedezd fel: Gẹn 22:2
3
Gẹn 22:12
O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo.
Fedezd fel: Gẹn 22:12
4
Gẹn 22:8
Abrahamu si wipe, Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ̀ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun: bẹ̃li awọn mejeji jùmọ nlọ.
Fedezd fel: Gẹn 22:8
5
Gẹn 22:17-18
Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn; Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.
Fedezd fel: Gẹn 22:17-18
6
Gẹn 22:1
O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi.
Fedezd fel: Gẹn 22:1
7
Gẹn 22:11
Angeli OLUWA nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: o si dahùn pe, Emi niyi.
Fedezd fel: Gẹn 22:11
8
Gẹn 22:15-16
Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji, O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo
Fedezd fel: Gẹn 22:15-16
9
Gẹn 22:9
Nwọn si de ibi ti Ọlọrun ti wi fun u; Abrahamu si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si to igi rere, o si dì Isaaki ọmọ rẹ̀, o si dá a bulẹ li ori pẹpẹ lori igi na.
Fedezd fel: Gẹn 22:9
Kezdőoldal
Biblia
Tervek
Videók