1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:9-10
Yoruba Bible
Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ, nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́, èrè wọn yóo sì pọ̀. Bí ọ̀kan bá ṣubú, ekeji yóo gbé e dìde. Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé! Nítorí nígbà tí ó bá ṣubú kò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde.
Compare
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:9-10
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:12
Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ, nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀. Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:12
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:11
Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀, wọn yóo fi ooru mú ara wọn ṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀?
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:11
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:6
Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyà ju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:6
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:4
Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:4
6
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:13
Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4:13
Home
Bible
Plans
Videos