YouVersion Logo
Search Icon

Eks 12:12-13

Eks 12:12-13 YBCV

Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA. Ẹ̀jẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹ̀jẹ na, emi o ré nyin kọja, iyọnu na ki yio wá sori nyin lati run nyin nigbati mo ba kọlù ilẹ Egipti.