Iṣe Apo 2:46-47
Iṣe Apo 2:46-47 YBCV
Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn. Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.