1
Saamu 37:4
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ṣe inú dídùn sí OLúWA; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
Compare
Explore Saamu 37:4
2
Saamu 37:5
Fi ọ̀nà rẹ lé OLúWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
Explore Saamu 37:5
3
Saamu 37:7
Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLúWA, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
Explore Saamu 37:7
4
Saamu 37:3
Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
Explore Saamu 37:3
5
Saamu 37:23-24
Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí OLúWA di ọwọ́ rẹ̀ mú.
Explore Saamu 37:23-24
6
Saamu 37:6
Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
Explore Saamu 37:6
7
Saamu 37:8
Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀, má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.
Explore Saamu 37:8
8
Saamu 37:25
Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
Explore Saamu 37:25
9
Saamu 37:1
Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀
Explore Saamu 37:1
Home
Bible
Plans
Videos