1
Òwe 1:7-8
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́. Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
Compare
Explore Òwe 1:7-8
2
Òwe 1:32-33
Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run; Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”
Explore Òwe 1:32-33
3
Òwe 1:5
Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
Explore Òwe 1:5
4
Òwe 1:10
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.
Explore Òwe 1:10
5
Òwe 1:1-4
Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀. Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè; láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
Explore Òwe 1:1-4
6
Òwe 1:28-29
“Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi. Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù OLúWA.
Explore Òwe 1:28-29
Home
Bible
Plans
Videos