Kora ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi àwọn ọmọ Reubeni: Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, àti Oni ọmọ Peleti mú ènìyàn mọ́ra. Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́tà-lé-nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.