Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta
èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLúWA ti mú àbùkù
àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ
tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi
nínú egungun mi
Agara dá mi ní inú mi
nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.