Ẹ̀mí OLúWA Olódùmarè wà lára mi
nítorí OLúWA ti fi ààmì òróró yàn mí
láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà.
Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
Láti kéde ọdún ojúrere OLúWA
àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
irúgbìn OLúWA
láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.