1
Isaiah 30:21
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”
Compare
Explore Isaiah 30:21
2
Isaiah 30:18
Síbẹ̀síbẹ̀ OLúWA sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí OLúWA jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!
Explore Isaiah 30:18
3
Isaiah 30:15
Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
Explore Isaiah 30:15
4
Isaiah 30:20
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.
Explore Isaiah 30:20
5
Isaiah 30:19
Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.
Explore Isaiah 30:19
6
Isaiah 30:1
“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni OLúWA wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀
Explore Isaiah 30:1
Home
Bible
Plans
Videos