1
Luk 3:21-22
Bibeli Mimọ
Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀, Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.
Compare
Explore Luk 3:21-22
2
Luk 3:16
Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin
Explore Luk 3:16
3
Luk 3:8
Nitorina ki ẹnyin ki o so eso ti o yẹ fun ironupiwada, ki ẹ má si ṣe bẹ̀rẹ si iwi ninu ara nyin pe, awa ni Abrahamu ni baba: ki emi ki o wi fun nyin, Ọlọrun le gbe ọmọ dide fun Abrahamu ninu okuta wọnyi.
Explore Luk 3:8
4
Luk 3:9
Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná.
Explore Luk 3:9
5
Luk 3:4-6
Bi a ti kọ ọ ninu iwe ọ̀rọ woli Isaiah pe, Ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ mu ipa-ọna rẹ̀ tọ́. Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna; Gbogbo enia ni yio si ri igbala Ọlọrun.
Explore Luk 3:4-6
Home
Bible
Plans
Videos