Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo:
Ṣugbọn ọjọ́ keje li ọjọ́-isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ, ati ohunọ̀sin rẹ kan, ati alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ; ki ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ki o le simi gẹgẹ bi iwọ.