O si ṣe bi ẹnipe ẹnikan, nigbati a gbọ́ ohùn awọn afunpè ati awọn akọrin, bi ohùn kan lati ma yìn, ati lati ma dupẹ fun Oluwa; nigbati nwọn si gbé ohùn wọn soke pẹlu ipè ati kimbali, ati ohun-elo orin, lati ma yìn Oluwa pe, O ṣeun; ãnu rẹ̀ si duro lailai: nigbana ni ile na kún fun awọsanmọ, ani ile Oluwa;
Tobẹ̃ ti awọn alufa kò le duro lati ṣiṣẹ ìsin nitori awọsanmọ na: nitori ogo Oluwa kún ile Ọlọrun.