1
I. A. Ọba 17:14
Bibeli Mimọ
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: Ikoko iyẹfun na kì yio ṣòfo, bẹni kólobo ororo na kì yio gbẹ, titi di ọjọ ti Oluwa yio rọ̀ òjo si ori ilẹ.
Compare
Explore I. A. Ọba 17:14
2
I. A. Ọba 17:1
ELIJAH ara Tiṣbi, lati inu awọn olugbe Gileadi, wi fun Ahabu pe, Bi Oluwa Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọ̀rọ mi.
Explore I. A. Ọba 17:1
3
I. A. Ọba 17:13
Elijah si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; lọ, ki o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi; ṣugbọn ki o tètekọ ṣe àkara kekere kan fun mi ninu rẹ̀ na, ki o si mu u fun mi wá, lẹhin na, ki o ṣe tirẹ ati ti ọmọ rẹ
Explore I. A. Ọba 17:13
4
I. A. Ọba 17:12
On si wipe, Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, emi kò ni àkara, ṣugbọn ikunwọ iyẹfun ninu ìkoko, ati ororo diẹ ninu kòlobo: si kiyesi i, emi nṣa igi meji jọ, ki emi ki o le wọle lọ, ki emi ki o si peṣe rẹ̀ fun mi, ati fun ọmọ mi, ki awa le jẹ ẹ, ki a si kú.
Explore I. A. Ọba 17:12
5
I. A. Ọba 17:9
Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ.
Explore I. A. Ọba 17:9
6
I. A. Ọba 17:16
Ikoko iyẹfun na kò ṣòfo, bẹ̃ni kólobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Elijah sọ.
Explore I. A. Ọba 17:16
7
I. A. Ọba 17:15
O si lọ, o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Elijah: ati on ati obinrin na, ati ile rẹ̀ jẹ li ọjọ pupọ̀.
Explore I. A. Ọba 17:15
8
I. A. Ọba 17:10
On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu.
Explore I. A. Ọba 17:10
9
I. A. Ọba 17:4
Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ.
Explore I. A. Ọba 17:4
10
I. A. Ọba 17:11
Bi o si ti nlọ bù u wá, o ke si i, o si wipe, Jọ̃, mu okele onjẹ diẹ fun mi wá lọwọ rẹ.
Explore I. A. Ọba 17:11
11
I. A. Ọba 17:6
Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na.
Explore I. A. Ọba 17:6
12
I. A. Ọba 17:7
O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.
Explore I. A. Ọba 17:7
13
I. A. Ọba 17:24
Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ̀ pe, enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe, ọ̀rọ Oluwa li ẹnu rẹ, otitọ ni.
Explore I. A. Ọba 17:24
14
I. A. Ọba 17:5
O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.
Explore I. A. Ọba 17:5
15
I. A. Ọba 17:22
Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji.
Explore I. A. Ọba 17:22
Home
Bible
Plans
Videos