1
MAKU 10:45
Yoruba Bible
Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”
Compare
Explore MAKU 10:45
2
MAKU 10:27
Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.”
Explore MAKU 10:27
3
MAKU 10:52
Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.
Explore MAKU 10:52
4
MAKU 10:9
Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà á.”
Explore MAKU 10:9
5
MAKU 10:21
Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.”
Explore MAKU 10:21
6
MAKU 10:51
Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”
Explore MAKU 10:51
7
MAKU 10:43
ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín
Explore MAKU 10:43
8
MAKU 10:15
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.”
Explore MAKU 10:15
9
MAKU 10:31
Ṣugbọn ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ẹni iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo wá di ẹni iwájú.”
Explore MAKU 10:31
10
MAKU 10:6-8
Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn. Nítorí èyí ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóo wá fi ara mọ́ iyawo rẹ̀; àwọn mejeeji yóo wá di ọ̀kan. Wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́ bíkòṣe ọ̀kan.
Explore MAKU 10:6-8
Home
Bible
Plans
Videos