1
AISAYA 38:5
Yoruba Bible
kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀.
Compare
Explore AISAYA 38:5
2
AISAYA 38:3
ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
Explore AISAYA 38:3
3
AISAYA 38:17
Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ; ìwọ ni o dì mí mú, tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun, nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé.
Explore AISAYA 38:17
4
AISAYA 38:1
Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”
Explore AISAYA 38:1
Home
Bible
Plans
Videos