1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:26
Yoruba Bible
Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.
Compare
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:26
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:24-25
Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá. Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:24-25
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:11
Lẹ́yìn náà, ni mo ro gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi, ati gbogbo làálàá mi lórí rẹ̀; sibẹ: mo wòye pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, kò sì sí èrè kankan láyé.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:11
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:10
Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:10
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:13
Mo wá rí i pé bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ ni ọgbọ́n dára ju ìwà wèrè lọ.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:13
6
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:14
Ọlọ́gbọ́n ní ojú lágbárí, ṣugbọn ninu òkùnkùn ni òmùgọ̀ ń rìn. Sibẹ mo rí i pé, nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:14
7
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:21
Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni.
Explore ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 2:21
Home
Bible
Plans
Videos