1
KỌRINTI KINNI 2:9
Yoruba Bible
Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́, Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí, ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.”
Compare
Explore KỌRINTI KINNI 2:9
2
KỌRINTI KINNI 2:14
Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé.
Explore KỌRINTI KINNI 2:14
3
KỌRINTI KINNI 2:10
Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun.
Explore KỌRINTI KINNI 2:10
4
KỌRINTI KINNI 2:12
Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa.
Explore KỌRINTI KINNI 2:12
5
KỌRINTI KINNI 2:4-5
Ọ̀rọ̀ mi ati iwaasu mi kì í ṣe láti fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ó dùn létí yi yín lọ́kàn pada, iṣẹ́ Ẹ̀mí ati agbára Ọlọrun ni mo fẹ́ fihàn; kí igbagbọ yín má baà dúró lórí ọgbọ́n eniyan bíkòṣe lórí agbára Ọlọrun.
Explore KỌRINTI KINNI 2:4-5
Home
Bible
Plans
Videos