1
JẸNẸSISI 13:15
Yoruba Bible
YCE
Gbogbo ilẹ̀ tí ò ń wò yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún títí lae.
አወዳድር
{{ጥቅስ}} ያስሱ
2
JẸNẸSISI 13:14
Lẹ́yìn tí Lọti ti kúrò lọ́dọ̀ Abramu, OLUWA sọ fún Abramu pé, “Gbé ojú rẹ sókè, kí o wò ó láti ibi tí o wà yìí, títí lọ sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, tún wò ó lọ sí ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn.
3
JẸNẸSISI 13:16
N óo mú kí àwọn ọmọ rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tí yóo fi jẹ́ pé, àfi ẹni tí ó bá lè ka iye erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóo lè kà wọ́n.
4
JẸNẸSISI 13:8
Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá?
5
JẸNẸSISI 13:18
Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA.
6
JẸNẸSISI 13:10
Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run.